Sekariah 11:1-9

Sekariah 11:1-9 YCB

Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lebanoni, kí iná bá lè jẹ igi kedari rẹ run, Hu, igi junifa; nítorí igi kedari ṣubú, nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́: hu, ẹ̀yin igi óákù tí Baṣani, nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀. Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn; ògo wọn bàjẹ́; gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jordani bàjẹ́. Báyìí ni OLúWA Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa. Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún OLúWA, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn. Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni OLúWA wí, “Ṣí kíyèsi í, èmi yóò fi olúkúlùkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.” Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì sọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran náà. Olùṣọ́-àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan. Ọkàn mi sì kórìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kórìíra mi. Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”