ṢI ilẹkun rẹ wọnni silẹ, Iwọ Lebanoni, ki iná ba le jẹ igi kedari rẹ run. Hu, igi firi; nitori igi kedari ṣubu; nitori ti a ba awọn alagbara jẹ: hu, ẹnyin igi oaku ti Baṣani, nitori a ke igbo ajara lulẹ. Ohùn igbe awọn oluṣọ agutan; nitori ogo wọn bajẹ: ohùn bibu awọn ọmọ kiniun; nitori ogo Jordani bajẹ. Bayi li Oluwa Ọlọrun mi wi; Bọ́ ọwọ́-ẹran abọ́pa. Ti awọn oluwa wọn npa wọn, ti nwọn kò si kà ara wọn si pe nwọn jẹbi: ati awọn ti ntà wọn wipe, Ibukún ni fun Oluwa, nitoriti mo di ọlọrọ̀: awọn oluṣọ agutan wọn kò si ṣãnu wọn. Nitori emi kì yio ṣãnu fun awọn ara ilẹ na mọ, li Oluwa wi; si kiye si i, emi o fi olukuluku enia le aladugbo rẹ̀ lọwọ, ati le ọwọ ọba rẹ̀: nwọn o si fọ́ ilẹ na, emi kì yio si gbà wọn lọwọ wọn. Emi o si bọ́ ẹran abọ́pa, ani ẹnyin otoṣi ninu ọwọ́ ẹran. Mo si mu ọpa meji sọdọ; mo pe ọkan ni Ẹwà, mo si pe ekeji ni Amure; mo si bọ́ ọwọ́-ẹran na. Oluṣọ agutan mẹta ni mo si ke kuro li oṣu kan; ọkàn mi si korira wọn, ọkàn wọn pẹlu si korira mi. Mo si wipe, emi kì yio bọ nyin: eyi ti nkú lọ, jẹ ki o kú; eyi ti a o ba si ke kuro, jẹ ki a ke e kuro; ki olukuluku ninu awọn iyokù jẹ ẹran-ara ẹnikeji rẹ̀.
Kà Sek 11
Feti si Sek 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sek 11:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò