Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ; nítorí èmi tí rà wọ́n padà; wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè: síbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jíjìn; wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà. Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Asiria: èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi àti Lebanoni; a a kì yóò sì rí ààyè fún wọn bí ó ti yẹ. Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já, yóò sì bori rírú omi nínú Òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀, ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò. Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú OLúWA; wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,” ni OLúWA wí.
Kà Sekariah 10
Feti si Sekariah 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sekariah 10:8-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò