Emi o kọ si wọn, emi o si ṣà wọn jọ; nitori emi ti rà wọn pada: nwọn o si rẹ̀ si i gẹgẹ bi wọn ti nrẹ̀ si i ri. Emi o si gbìn wọn lãrin awọn enia: nwọn o si ranti mi ni ilẹ jijin; nwọn o si wà pẹlu awọn ọmọ wọn, nwọn o si tún pada. Emi o si tún mu wọn pada kuro ni ilẹ Egipti pẹlu, emi o si ṣà wọn jọ kuro ni ilẹ Assiria: emi o si mu wọn wá si ilẹ Gileadi ati Lebanoni; a kì yio si ri àye fun wọn. Yio si là okun wahala ja, yio si lù riru omi ninu okun, gbogbo ibu odò ni yio si gbẹ, a o si rẹ̀ igberaga Assiria silẹ, ọpa alade Egipti yio si lọ kuro. Emi o si mu wọn le ninu Oluwa; nwọn o si rìn soke rìn sodò li orukọ rẹ̀, ni Oluwa wi.
Kà Sek 10
Feti si Sek 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sek 10:8-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò