Saamu 31:1-11

Saamu 31:1-11 YCB

Nínú rẹ̀, OLúWA ni mo ti rí ààbò; Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ. Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi. Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, OLúWA, Ọlọ́run òtítọ́. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé OLúWA. Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú. Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá. Ṣàánú fún mi, ìwọ OLúWA, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú. Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù. Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi; àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.