O. Daf 31:1-11

O. Daf 31:1-11 YBCV

OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi: gbà mi ninu ododo rẹ. Dẹ eti rẹ silẹ si mi: gbà mi nisisiyi: iwọ ma ṣe apata agbara mi, ile-ãbò lati gba mi si. Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: nitorina nitori orukọ rẹ ma ṣe itọ́ mi, ki o si ma ṣe amọ̀na mi. Yọ mi jade ninu àwọn ti nwọn nà silẹ fun mi ni ìkọkọ: nitori iwọ li ãbo mi. Li ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le: iwọ li o ti rà mi pada, Oluwa Ọlọrun otitọ. Emi ti korira awọn ẹniti nfiyesi eke asan: ṣugbọn emi gbẹkẹle Oluwa. Emi o yọ̀, inu mi yio si dùn ninu ãnu rẹ: nitori ti iwọ ti rò ti iṣẹ́ mi; iwọ ti mọ̀ ọkàn mi ninu ipọnju; Iwọ kò si sé mi mọ́ si ọwọ ọta nì: iwọ fi ẹsẹ mi tẹlẹ ni ibi àye nla. Ṣãnu fun mi, Oluwa, nitori ti emi wà ninu iṣẹ́: oju mi fi ibinujẹ run, ọkàn mi ati inu mi. Emi fi ibinujẹ lò ọjọ mi, ati ọdun mi ti on ti imi-ẹ̀dun: agbara mi kú nitori ẹ̀ṣẹ mi, awọn egungun mi si run. Emi di ẹni-ẹ̀gan lãrin awọn ọta mi gbogbo, pẹlupẹlu lãrin awọn aladugbo mi, mo si di ẹ̀ru fun awọn ojulumọ mi: awọn ti o ri mi lode nyẹra fun mi.