Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, OLúWA,
èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
níbikíbi tí èmi ń gbé.
Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, OLúWA,
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
nítorí tí mo
gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
Ìwọ ni ìpín mi, OLúWA:
èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
nítorí òfin òdodo rẹ.
Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, OLúWA,
kọ́ mi ní òfin rẹ.
Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA.
Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
Èmi mọ, OLúWA, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
tí ó lòdì sí òfin rẹ.
Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé;
ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
Ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA, títí láé ni;
ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.
Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
Òfin rẹ dúró di òní
nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.
Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.
Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.