O. Daf 119:49-104
O. Daf 119:49-104 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́. Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ. Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́. Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ. Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo. Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ. O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ. Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ. Ọwọ rẹ li o ti da mi, ti o si ṣe àworan mi: fun mi li oye, ki emi ki o le kọ́ aṣẹ rẹ. Inu awọn ti o bẹ̀ru rẹ yio dùn, nigbati nwọn ba ri mi; nitori ti mo ti reti li ọ̀rọ rẹ. Oluwa, emi mọ̀ pe, ododo ni idajọ rẹ, ati pe li otitọ ni iwọ pọ́n mi loju. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iṣeun-ãnu rẹ ki o mã ṣe itunu mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ si iranṣẹ rẹ. Jẹ ki irọnu ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didùn-inu mi. Jẹ ki oju ki o tì agberaga; nitori ti nwọn ṣe arekereke si mi li ainidi: ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ. Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru rẹ ki o yipada si mi, ati awọn ti o ti mọ̀ ẹri rẹ. Jẹ ki aiya mi ki o pé ni ilana rẹ; ki oju ki o máṣe tì mi. Ọkàn mi ndaku fun igbala rẹ; ṣugbọn emi ni ireti li ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣofo nitori ọ̀rọ rẹ, wipe, Nigbawo ni iwọ o tù mi ninu? Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ. Ijọ melo li ọjọ iranṣẹ rẹ? nigbawo ni iwọ o ṣe idajọ lara awọn ti nṣe inunibini si mi? Awọn agberaga ti wà ìho silẹ dè mi, ti kì iṣe gẹgẹ bi ofin rẹ. Otitọ li aṣẹ rẹ gbogbo: nwọn fi arekereke ṣe inunibini si mi: iwọ ràn mi lọwọ. Nwọn fẹrẹ run mi li ori ilẹ; ṣugbọn emi kò kọ ẹkọ́ rẹ silẹ. Sọ mi di ãye gẹgẹ bi iṣeun-ãnu rẹ; bẹ̃li emi o pa ẹri ẹnu rẹ mọ́. Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun. Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro. Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi. Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye. Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ. Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ. Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi. Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo. Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai. Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi. Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi. Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi! Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo.
O. Daf 119:49-104 Yoruba Bible (YCE)
Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ, èyí tí ó fún mi ní ìrètí. Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé: ìlérí rẹ mú mi wà láàyè. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi, ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́, OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀. Inú mi á máa ru, nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú, tí wọn ń rú òfin rẹ. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ, lákòókò ìrìn àjò mi láyé. Mo ranti orúkọ rẹ lóru; OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́: Èyí ni ìṣe mi: Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní; mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ, ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi, mo yipada sí ìlànà rẹ; mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi, n kò ní gbàgbé òfin rẹ. Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́, nítorí ìlànà òdodo rẹ. Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí, àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé, nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ; ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́. Ọkàn wọn ti yigbì, ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani, ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ. Òfin rẹ níye lórí fún mi, ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ. Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi, fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ. Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà, ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ. Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè, nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga, nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí; ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá, kí wọ́n lè mọ òfin rẹ. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé, kí ojú má baà tì mí. Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi; ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ. Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?” Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì, sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi? Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí, àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́. Gbogbo òfin rẹ ló dájú; ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi. Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run. Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran; o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró. Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní, nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi, ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú. Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ, nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé. Ìwọ ni o ni mí, gbà mí; nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn eniyan burúkú ba dè mí, wọ́n fẹ́ pa mí run, ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán, àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin. Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ! Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ, nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ, nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. N kò rin ọ̀nà ibi kankan, kí n lè pa òfin rẹ mọ́. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ, nítorí pé o ti kọ́ mi. Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ, ó dùn ju oyin lọ. Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye, nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.
O. Daf 119:49-104 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí. Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́. Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ. Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, OLúWA, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn. Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀. Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé. Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, OLúWA, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́. Ìwọ ni ìpín mi, OLúWA: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ. Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ. Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo rẹ. Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ. Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, OLúWA, kọ́ mi ní òfin rẹ. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA. Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ. Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ. Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ. Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ. Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí; fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi mọ, OLúWA, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú. Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ. Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi. Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pa mí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ. Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi, àwọn tí ó ní òye òfin rẹ. Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí. Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ. Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí? Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin rẹ. Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé; ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí. Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ. Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run. Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin. Òfin rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́. Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi. Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́. Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ. Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni. Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá. Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé. Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ. Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi. Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi! Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.