Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé OLúWA lọ́wọ́, èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe. OLúWA ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú. OLúWA kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà. Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù OLúWA ènìyàn sá fún ibi. Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ OLúWA lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà. Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ. Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n OLúWA ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀. Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké. Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́ nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀. Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́, wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́. Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú. Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò. Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!
Kà Òwe 16
Feti si Òwe 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Òwe 16:3-16
4 Days
The Bible commands us to work hard, but it also tells us that it is God—not us—who produces results through our work. As this four day plan will show, the Christian professional must embrace the tension between “trusting” and “hustling” in order to find true Sabbath rest.
A new year has arrived and with it, new goals and resolutions that we want to achieve. Everything has changed in the world; however, we have the same almighty God who is able to give us a blessed year. Join me in these 4 days that will help us to start a year with purpose.
Join David Villa in his latest devotional as he discusses the profound implications that committing our work to the Lord has for our lives.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò