Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ. Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi. Olukulùku enia ti o gberaga li aiya, irira ni loju Oluwa: bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, kì yio wà laijiya. Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi. Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia. Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́. Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀. Ọrọ isọtẹlẹ mbẹ li ète ọba: ẹnu rẹ̀ kì iṣẹ̀ ni idajọ. Iwọn ati òṣuwọn otitọ ni ti Oluwa: gbogbo okuta-ìwọn àpo, iṣẹ rẹ̀ ni. Irira ni fun awọn ọba lati ṣe buburu: nitoripe nipa ododo li a ti fi idi itẹ́ kalẹ. Ete ododo ni didùn-inu awọn ọba: nwọn si fẹ ẹniti nsọ̀rọ titọ. Ibinu ọba dabi iranṣẹ ikú: ṣugbọn ọlọgbọ́n enia ni yio tù u. Ni imọlẹ oju ọba ni ìye; ojurere rẹ̀ si dabi awọsanma òjo arọkuro. Lati ni ọgbọ́n, melomelo li o san jù wura lọ; ati lati ni oye, melomelo li o dara jù fadaka lọ.
Kà Owe 16
Feti si Owe 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 16:3-16
4 Days
The Bible commands us to work hard, but it also tells us that it is God—not us—who produces results through our work. As this four day plan will show, the Christian professional must embrace the tension between “trusting” and “hustling” in order to find true Sabbath rest.
A new year has arrived and with it, new goals and resolutions that we want to achieve. Everything has changed in the world; however, we have the same almighty God who is able to give us a blessed year. Join me in these 4 days that will help us to start a year with purpose.
Join David Villa in his latest devotional as he discusses the profound implications that committing our work to the Lord has for our lives.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò