Filipi 2:16-18

Filipi 2:16-18 YCB

Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán. Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.