Filp 2:16-18
Filp 2:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le ṣogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si ṣe lãlã lasan. Ani, bi a tilẹ tú mi dà sori ẹbọ ati iṣẹ isin igbagbọ́ nyin, mo yọ̀, mo si mba gbogbo nyin yọ̀ pẹlu. Bakanna ni ki ẹnyin ki o mã yọ̀, ki ẹ si mã ba mi yọ̀ pẹlu.

Filp 2:16-18 Yoruba Bible (YCE)
tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo. Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín. Nítorí náà, kí inú yín kí ó máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.
Filp 2:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán. Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.