Numeri 26:1-25

Numeri 26:1-25 YCB

Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn OLúWA sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.” Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé, “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá: Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá; Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá; ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni; ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (43,730). Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu, àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá OLúWA jà. Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀. Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú. Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini; ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-igba. (22,200) ọkùnrin. Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn: ti Sefoni, ìdílé Sefoni; ti Haggi, ìdílé Haggi; ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni; ti Osni, ìdílé Osni; ti Eri, ìdílé Eri; ti Arodi, ìdílé Arodi; ti Areli, ìdílé Areli. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani. Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣela, ìdílé Ṣela; ti Peresi, ìdílé Peresi; ti Sera, ìdílé Sera. Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu. Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlógójì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500). Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa; ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni. Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (64,300).