Num 26:1-25
Num 26:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe lẹhin àrun na, ni OLUWA sọ fun Mose ati fun Eleasari alufa ọmọ Aaroni pe, Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli. Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe, Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá. Reubeni, akọ́bi Israeli: awọn ọmọ Reubeni; Hanoki, lati ọdọ ẹniti idile awọn ọmọ Hanoki ti wá: ti Pallu, idile awọn ọmọ Pallu: Ti Hesroni, idile awọn ọmọ Hesroni: ti Karmi, idile awọn ọmọ Karmi. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Reubeni: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanlelogun o le ẹgbẹsan o din ãdọrin. Ati awọn ọmọ Pallu; Eliabu. Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà. Ti ilẹ si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì pọ̀ pẹlu Kora, nigbati ẹgbẹ na fi kú, nigbati iná fi run awọn ãdọtalerugba ọkunrin, ti nwọn si di àmi kan. Ṣugbọn awọn ọmọ Kora kò kú. Awọn ọmọ Simeoni bi idile wọn: ti Nemueli, idile Nemueli: ti Jamini, idile Jamini: ti Jakini, idile Jakini: Ti Sera, idile Sera: ti Ṣaulu, idile Ṣaulu. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Simeoni, ẹgba mọkanla o le igba. Awọn ọmọ Gadi bi idile wọn: ti Sefoni, idile Sefoni: ti Haggi, idile Haggi: ti Ṣuni, idile Ṣuni: Ti Osni, idile Osni: ti Eri, idile Eri: Ti Arodu, idile Arodu: ti Areli, idile Areli. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani. Ati awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn; ti Ṣela, idile Ṣela: ti Peresi, idile Peresi: ti Sera, idile Sera. Awọn ọmọ Peresi; ti Hesroni, idile Hesroni: ti Hamulu, idile Hamulu. Wọnyi ni idile Juda gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejidilogoji o le ẹdẹgbẹta. Awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn: ti Tola, idile Tola: ti Pufa, idile Pufa: Ti Jaṣubu, idile Jaṣubu: ti Ṣimroni, idile Ṣimroni. Wọnyi ni idile Issakari gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le ọdunrun.
Num 26:1-25 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn náà, OLUWA sọ fún Mose ati Eleasari alufaa ọmọ Aaroni pé, “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.” Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí: Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu, ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730). Palu bí Eliabu, Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA. Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kora kò kú. Àwọn ọmọ Simeoni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Nemueli, ìdílé Jamini, ati ìdílé Jakini; ìdílé Sera ati ti Ṣaulu. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba (22,200). Àwọn ọmọ Gadi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Sefoni, ìdílé Hagi, ati ìdílé Ṣuni; ìdílé Osini, ati ìdílé Eri; ìdílé Arodu ati ìdílé Areli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Gadi jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500). Àwọn ọmọ Juda ni Eri ati Onani. Eri ati Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani. Àwọn ọmọ Juda ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣela, ìdílé Peresi, ati ìdílé Sera. Àwọn ọmọ Peresi nìwọ̀nyí: ìdílé Hesironi ati ìdílé Hamuli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbaa mejidinlogoji ó lé ẹẹdẹgbẹta (76,500). Àwọn ọmọ Isakari ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Tola, ìdílé Pua; ìdílé Jaṣubu ati ìdílé Ṣimironi. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé ọọdunrun (64,300).
Num 26:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn OLúWA sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.” Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé, “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá: Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá; Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá; ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni; ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (43,730). Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu, àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá OLúWA jà. Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀. Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú. Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini; ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-igba. (22,200) ọkùnrin. Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn: ti Sefoni, ìdílé Sefoni; ti Haggi, ìdílé Haggi; ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni; ti Osni, ìdílé Osni; ti Eri, ìdílé Eri; ti Arodi, ìdílé Arodi; ti Areli, ìdílé Areli. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani. Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣela, ìdílé Ṣela; ti Peresi, ìdílé Peresi; ti Sera, ìdílé Sera. Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu. Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlógójì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500). Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa; ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni. Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (64,300).