Ẹkun Jeremiah 3:22-27

Ẹkun Jeremiah 3:22-27 YCB

Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́. Dídára ni OLúWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà OLúWA. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.