Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀
ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀.
Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́
àwọn odi ààfin rẹ̀;
wọ́n sì kígbe ní ilé OLúWA
gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn.
OLúWA pinnu láti fa
ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya.
Ó gbé wọn sórí òṣùwọ̀n,
kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.
Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀
wọ́n ṣòfò papọ̀.
Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;
òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.
Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
kò sí òfin mọ́,
àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí
ìran láti ọ̀dọ̀ OLúWA mọ́.
Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni
jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;
wọ́n da eruku sí orí wọn
wọ́n sì wọ aṣọ àkísà.
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu
ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.
Ojú mi kọ̀ láti sọkún,
mo ń jẹ ìrora nínú mi,
mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀
nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,
nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú
ní òpópó ìlú.
Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,
“Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó
bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe
ní àwọn òpópónà ìlú,
bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò
láti ọwọ́ ìyá wọn.
Kí ni mo le sọ fún ọ?
Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,
Ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?
Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,
kí n lè tù ọ́ nínú,
Ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?
Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.
Ta ni yóò wò ọ́ sàn?
Ìran àwọn wòlíì rẹ
jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;
wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn
tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.
Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ
jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.
Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ
pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;
wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn
sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní
àṣepé ẹwà,
ìdùnnú gbogbo ayé?”
Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn
gbòòrò sí ọ;
wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke
wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.
Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;
tí a sì wá láti rí.”
OLúWA ti ṣe ohun tí ó pinnu;
ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,
tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.
Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,
ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,
ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.
Ọkàn àwọn ènìyàn
kígbe jáde sí OLúWA.
Odi ọmọbìnrin Sioni,
jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò
ní ọ̀sán àti òru;
má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,
ojú rẹ fún ìsinmi.
Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́,
bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀
tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi
níwájú OLúWA.
Gbé ọwọ́ yín sókè sí i
nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀
tí ó ń kú lọ nítorí ebi
ní gbogbo oríta òpópó.
“Wò ó, OLúWA, kí o sì rò ó:
Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí
Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,
àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún?
Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì
ní ibi mímọ́ OLúWA?
“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀
sínú eruku àwọn òpópó;
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi
ti ṣègbé nípa idà.
Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ;
Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.
“Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè,
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.
Ní ọjọ́ ìbínú OLúWA
kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;
àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,
ni ọ̀tá mi parun.”