Ẹk. Jer 2:7-22
Ẹk. Jer 2:7-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ tì, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi ogiri ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pa ariwo ninu ile Oluwa, gẹgẹ bi li ọjọ ajọ-mimọ́. Oluwa ti rò lati pa odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn ìwọn jade, on kò ti ifa ọwọ rẹ̀ sẹhin kuro ninu ipanirun: bẹ̃ni o ṣe ki ile-iṣọ rẹ̀ ati odi rẹ̀ ki o ṣọ̀fọ; nwọn jumọ rẹ̀ silẹ. Ẹnu-bode rẹ̀ wọnni rì si ilẹ; o ti parun o si ṣẹ́ ọpá idabu rẹ̀; ọba rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀ wà lãrin awọn orilẹ-ède: ofin kò si mọ; awọn woli rẹ̀ pẹlu kò ri iran lati ọdọ Oluwa. Awọn àgbagba ọmọbinrin Sioni joko ni ilẹ, nwọn dakẹ: nwọn ti ku ekuru sori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu sọ ori wọn kọ́ si ilẹ. Oju mi gbẹ tan fun omije, inu mi nho, a dà ẹ̀dọ mi sori ilẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi: nitoripe awọn ọmọ wẹ̃rẹ ati awọn ọmọ-ọmu nkulọ ni ita ilu na. Nwọn nsọ fun iya wọn pe, Nibo ni ọka ati ọti-waini gbe wà? nigbati nwọn daku gẹgẹ bi awọn ti a ṣalọgbẹ ni ita ilu na, nigbati ọkàn wọn dà jade li aiya iya wọn. Kili ohun ti emi o mu fi jẹri niwaju rẹ? kili ohun ti emi o fi ọ we, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu? kili emi o fi ba ọ dọgba, ki emi ba le tù ọ ninu, iwọ wundia ọmọbinrin Sioni? nitoripe ọgbẹ rẹ tobi gẹgẹ bi okun; tali o le wò ọ sàn? Awọn woli rẹ ti riran ohun asan ati wère fun ọ: nwọn kò si ti fi aiṣedede rẹ hàn ọ, lati yi igbekun rẹ pada kuro; ṣugbọn nwọn ti riran ọ̀rọ-wiwo eke fun ọ ati imuniṣina. Gbogbo awọn ti nkọja patẹwọ le ọ; nwọn nṣẹsin, nwọn si nmì ori wọn si ọmọbinrin Jerusalemu; pe, Ilu na ha li eyi, ti a npè ni: Pipe-ẹwà, Ayọ̀ gbogbo ilẹ aiye! Gbogbo awọn ọta rẹ ya ẹnu wọn si ọ; nwọn nṣe ṣiọ! nwọn si npa ehin keke, nwọn wipe: Awa ti gbe e mì; dajudaju eyi li ọjọ na ti awa ti nwọ̀na fun; ọwọ ti tẹ̀ ẹ, awa ti ri i! Oluwa ti ṣe eyi ti o ti rò; o ti mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti paṣẹ li ọjọ igbãni: o ti bì ṣubu, kò si dasi: o si ti mu ọta yọ̀ lori rẹ, o ti gbe iwo awọn aninilara rẹ soke. Ọkàn wọn kigbe si Oluwa, iwọ odi ọmọbinrin Sioni, jẹ ki omije ṣan silẹ gẹgẹ bi odò lọsan ati loru; má fun ara rẹ ni isimi; máṣe jẹ ki ẹyin oju rẹ gbe jẹ. Dide, kigbe soke li oru ni ibẹrẹ akoko iṣọ: tú ọkàn rẹ jade gẹgẹ bi omi niwaju Oluwa: gbe ọwọ rẹ soke si i fun ẹmi awọn ọmọ wẹwẹ rẹ, ti nkulọ fun ebi ni gbogbo ori-ita. Wò o, Oluwa, ki o rò, fun tani iwọ ti ṣe eyi? Awọn obinrin ha le ma jẹ eso-inu wọn, awọn ọmọ-ọwọ ti nwọn npọ̀n? a ha le ma pa alufa ati woli ni ibi mimọ́ Oluwa? Ewe ati arugbo dubulẹ ni ita wọnni: awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi ṣubu nipa idà: iwọ ti pa li ọjọ ibinu rẹ; iwọ ti pa, iwọ kò si dasi. Iwọ ti kepe ẹ̀ru mi yikakiri gẹgẹ bi li ọjọ mimọ́, tobẹ̃ ti ẹnikan kò sala tabi kì o kù li ọjọ ibinu Oluwa: awọn ti mo ti pọ̀n ti mo si tọ́, ni ọta mi ti run.
Ẹk. Jer 2:7-22 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́, ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀. OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀. Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, kò sì rowọ́ láti parun. Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, wọ́n sì di àlàpà papọ̀. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì, wọ́n ti wọlẹ̀; ó ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè; ọba rẹ̀ ati àwọn olórí rẹ̀ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn; òfin kò sí mọ́, àwọn wolii rẹ̀ kò sì ríran láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́. Àwọn àgbààgbà Sioni jókòó lórí ilẹ̀, wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ku eruku sórí, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu doríkodò. Ẹkún sísun ti sọ ojú mi di bàìbàì, ìdààmú bá ọkàn mi; ìbànújẹ́ sì mú kí ó rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìparun àwọn eniyan mi, nítorí pé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn ọmọ ọwọ́ ń dákú lójú pópó láàrin ìlú. Bí wọ́n ti ń dákú láàrin ìlú, bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́, tí wọ́n sì ń kú lọ lẹ́yìn ìyá wọn, wọ́n ń sọkún sí àwọn ìyá wọn pé: “Ebi ń pa wá, òùngbẹ sì ń gbẹ wá.” Kí ni mo lè sọ nípa rẹ, kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu? Kí ni mo lè fi wé ọ, kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni? Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò; ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò? Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ; wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́, kí wọ́n lè dá ire rẹ pada, ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ. Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọ ń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, wọ́n ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu. Wọ́n ń sọ pé: “Ṣé ìlú yìí ni à ń pè ní ìlú tí ó lẹ́wà jùlọ, tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?” Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ọ́ ṣẹ̀sín, wọ́n ń pòṣé, wọ́n ń fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń wí pé: “A ti pa á run! Ọjọ́ tí a tí ń retí nìyí; ọwọ́ wa ti tẹ Jerusalẹmu wàyí! A ti rí ohun tí à ń wá!” OLUWA ti ṣe bí ó ti pinnu, ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, bí ó ti sọ ní ìgbà àtijọ́. Ó ti wó ọ lulẹ̀ láìṣàánú rẹ; ó ti jẹ́ kí ọ̀tá yọ̀ ọ́, ó ti fún àwọn ọ̀tá rẹ ni agbára kún agbára. Ẹ kígbe sí OLUWA, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ jẹ́ kí omi máa dà lójú yín pòròpòrò tọ̀sán-tòru; ẹ má sinmi, ẹ má sì jẹ́ kí oorun kùn yín. Ẹ dìde, ẹ kígbe lálẹ́, ní àkókò tí àwọn aṣọ́de ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́! Ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín jáde bí omi níwájú OLUWA! Ẹ gbé ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sókè sí i, nítorí ẹ̀mí àwọn ọmọ yín tí ebi ń pa kú lọ ní gbogbo ìkóríta. Wò ó! OLUWA, ṣe akiyesi ohun tí ń ṣẹlẹ̀! Wo àwọn tí ò ń ṣe irú èyí sí! Ṣé ó yẹ kí àwọn obinrin máa jẹ ọmọ wọn? Ọmọ ọwọ́ tí wọn ń tọ́jú! Ṣé ó yẹ kí á pa alufaa ati wolii, ní ibi mímọ́ OLUWA? Àtàwọn ọ̀dọ́, àtàwọn arúgbó wọ́n kú kalẹ̀ lọ lójú pópó, àtàwọn ọdọmọbinrin, àtàwọn ọdọmọkunrin mi, gbogbo wọn ni idà ti pa. Ní ọjọ́ ibinu rẹ ni o pa wọ́n, o pa wọ́n ní ìpakúpa láìṣàánú wọn. O pe àwọn ọ̀tá mi jọ sí mi bí ẹni peniyan síbi àjọ̀dún; kò sì sí ẹni tí ó yè ní ọjọ́ ibinu rẹ, OLUWA. Ọ̀tá mi pa àwọn ọmọ mi run, àwọn tí mo tọ́, tí mo sì fẹ́ràn.
Ẹk. Jer 2:7-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀. Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀; wọ́n sì kígbe ní ilé OLúWA gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn. OLúWA pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya. Ó gbé wọn sórí òṣùwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀. Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ OLúWA mọ́. Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́; wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀. Ojú mi kọ̀ láti sọkún, mo ń jẹ ìrora nínú mi, mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀ nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run, nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú ní òpópó ìlú. Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, “Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn. Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé, Ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, Ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni? Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn? Ìran àwọn wòlíì rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n; wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ. Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà. Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí; wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu: “Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní àṣepé ẹwà, ìdùnnú gbogbo ayé?” Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn gbòòrò sí ọ; wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán. Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí; tí a sì wá láti rí.” OLúWA ti ṣe ohun tí ó pinnu; ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́. Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú, ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ, ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga. Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí OLúWA. Odi ọmọbìnrin Sioni, jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò ní ọ̀sán àti òru; má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi. Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú OLúWA. Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó. “Wò ó, OLúWA, kí o sì rò ó: Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún? Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ OLúWA? “Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà. Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ; Ìwọ pa wọ́n láìní àánú. “Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi. Ní ọjọ́ ìbínú OLúWA kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè; àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn, ni ọ̀tá mi parun.”