Joẹli 1:1-13

Joẹli 1:1-13 YCB

Ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá. Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà; ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà. Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín? Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín, ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn, ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn. Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù ní ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá ti jẹ, èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá jẹ kù ní eṣú kéékèèkéé jẹ Èyí tí eṣú kéékèèkéé jẹ kù ni eṣú apanirun mìíràn jẹ. Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì; ẹ hu nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín. Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún. Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun. Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀. A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò ní ilé OLúWA; àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìránṣẹ́ OLúWA, Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe. Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí alikama àti nítorí ọkà barle; nítorí ìkórè oko ṣègbé. Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ: Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.