Joel 1:1-13

Joel 1:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Joeli ọmọ Petueli wá. Gbọ́ eyi, ẹnyin arugbo, si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ na. Eyi ha wà li ọjọ nyin, tabi li ọjọ awọn baba nyin? Ẹ sọ ọ fun awọn ọmọ nyin, ati awọn ọmọ nyin fun awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ wọn fun iran miràn. Eyi ti iru kòkoro kan jẹ kù ni ẽṣú jẹ; ati eyi ti ẽṣú jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ; eyiti kòkoro na si jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ. Ji, ẹnyin ọmùti, ẹ si sọkun; si hu, gbogbo ẹnyin ọmùti waini, nitori ọti-waini titun; nitoriti a ké e kuro li ẹnu nyin. Nitori orilẹ-ède kan goke wá si ilẹ mi, o li agbara, kò si ni iye, ehin ẹniti iṣe ehin kiniun, o si ni erìgi abo kiniun. O ti pa àjara mi run, o si ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọtọ́ mi kuro, o ti bó o jalẹ, o si sọ ọ nù; awọn ẹ̀ka rẹ̀ li a si sọ di funfun. Ẹ pohùnrére-ẹkun bi wundia ti a fi aṣọ ọ̀fọ dì li àmure, nitori ọkọ igbà ewe rẹ̀. A ké ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu kuro ni ile Oluwa; awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, ṣọ̀fọ. Oko di ìgboro, ilẹ nṣọ̀fọ, nitori a fi ọkà ṣòfo: ọti-waini titun gbẹ, ororo mbuṣe. Ki oju ki o tì nyin, ẹnyin agbẹ̀; ẹ hu, ẹnyin olùtọju àjara, nitori alikamà ati nitori ọkà barli; nitori ikorè oko ṣègbe. Ajara gbẹ, igi ọ̀pọtọ́ si rọgbẹ; igi pomegranate, igi ọ̀pẹ pẹlu, ati igi appili, gbogbo igi igbo li o rọ: nitoriti ayọ̀ rọgbẹ kuro lọdọ awọn ọmọ enia. Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin.

Joel 1:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Iṣẹ́ tí OLUWA rán Joẹli, ọmọ Petueli nìyí: Ẹ gbọ́, ẹ̀yin àgbà, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí! Ǹjẹ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ rí ní àkókò yín, tabi ní àkókò àwọn baba yín? Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín nípa rẹ̀, kí àwọn náà sọ fún àwọn ọmọ wọn, kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún àwọn ọmọ tiwọn náà. Ohun tí eṣú wẹẹrẹ jẹ kù, ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ ẹ́. Èyí tí ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ kù, àwọn eṣú wẹẹrẹ mìíràn jẹ ẹ́, èyí tí àwọn eṣú wẹẹrẹ yìí jẹ kù, àwọn eṣú tí ń jẹ nǹkan run jẹ ẹ́ tán. Ẹ jí lójú oorun, ẹ̀yin ọ̀mùtí, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń mu waini, nítorí waini tuntun tí a já gbà kúrò lẹ́nu yín. Orílẹ̀-èdè kan ti dojú kọ ilẹ̀ mi, wọ́n lágbára, wọ́n pọ̀, wọn kò sì lóǹkà; eyín wọn dàbí ti kinniun. Ọ̀gàn wọn sì dàbí ti abo kinniun. Wọ́n ti run ọgbà àjàrà mi, wọ́n ti já àwọn ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi, wọ́n ti bó gbogbo èèpo ara rẹ̀, wọ́n ti wó o lulẹ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ti di funfun. Ẹ sọkún bí ọmọge tí ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, nítorí ikú àfẹ́sọ́nà ìgbà èwe rẹ̀. A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA, àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀. Ilẹ̀ ti gbẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ti run ọkà, àjàrà ti tán, epo olifi sì ń tán lọ. Ẹ banújẹ́, ẹ̀yin àgbẹ̀, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ẹ̀yin tí ẹ̀ ń tọ́jú ọgbà àjàrà, nítorí ọkà alikama ati ọkà baali, ati nítorí pé ohun ọ̀gbìn ti ṣègbé. Èso àjàrà ti rọ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti ń gbẹ. Igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ ati igi ápù, ati gbogbo àwọn igi eléso ti gbẹ, inú ọmọ eniyan kò sì dùn mọ́. Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ. Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn, nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.

Joel 1:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá. Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà; ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà. Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín? Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín, ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn, ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn. Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù ní ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá ti jẹ, èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá jẹ kù ní eṣú kéékèèkéé jẹ Èyí tí eṣú kéékèèkéé jẹ kù ni eṣú apanirun mìíràn jẹ. Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì; ẹ hu nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín. Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún. Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun. Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀. A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò ní ilé OLúWA; àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìránṣẹ́ OLúWA, Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe. Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí alikama àti nítorí ọkà barle; nítorí ìkórè oko ṣègbé. Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ: Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.