“Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu
wò yíká, kí o sì mọ̀,
kí o sì wá kiri
Bí o bá le è rí ẹnìkan,
tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo,
n ó dáríjì ìlú yìí.
Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí OLúWA ti ń bẹ,’
síbẹ̀ wọ́n búra èké.”
OLúWA, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́
Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n.
Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà.
Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ,
wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.
Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí;
wọn jẹ́ aṣiwèrè,
nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà OLúWA,
àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.
Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,
n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;
ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà OLúWA
àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,
wọ́n sì ti já ìdè.
Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,
ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run,
ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín
ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,
ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.
“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?
Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀
àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.
Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn,
síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà
wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.
Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,
tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.
Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?”
ni OLúWA wí.
“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi
lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?
“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,
ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá.
Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,
nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti OLúWA.
Ilé Israẹli àti ilé Juda
ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,”
ni OLúWA wí.
Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ OLúWA;
wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan!
Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá;
àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.
Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,
ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.
Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”