Jer 5:1-13

Jer 5:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹrìn kiri la ita Jerusalemu ja, ki ẹ si wò nisisiyi, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si wakiri nibi gbigbòro rẹ̀, bi ẹ ba lè ri ẹnikan, bi ẹnikan wà ti nṣe idajọ, ti o nwá otitọ; emi o si dari ji i. Bi nwọn ba si wipe, Oluwa mbẹ; sibẹ nwọn bura eke. Oluwa, oju rẹ kò ha wà lara otitọ? iwọ ti lù wọn, ṣugbọn kò dùn wọn; iwọ ti run wọn, ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gba ẹkọ: nwọn ti mu oju wọn le jù apata lọ; nwọn kọ̀ lati yipada. Emi si wipe, Lõtọ talaka enia ni awọn wọnyi, nwọn kò ni oye, nitori nwọn kò mọ̀ ọ̀na Oluwa, tabi idajọ Ọlọrun wọn. Emi o tọ̀ awọn ẹni-nla lọ, emi o si ba wọn sọrọ; nitori nwọn ti mọ̀ ọ̀na Oluwa, idajọ Ọlọrun wọn. Ṣugbọn awọn wọnyi ti jumọ ṣẹ́ àjaga, nwọn si ti ja ìde. Nitorina kiniun lati inu igbo wa yio pa wọn, ikõko aṣálẹ̀ yio pa wọn run, ẹkùn yio mã ṣọ ilu wọn: ẹnikẹni ti o ba ti ibẹ jade li a o ya pẹrẹpẹrẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wọn pọ̀, ati ipẹhinda wọn le. Emi o ha ṣe dari eyi ji ọ? awọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si fi eyi ti kì iṣe ọlọrun bura: emi ti mu wọn bura, ṣugbọn nwọn ṣe panṣaga, nwọn si kó ara wọn jọ si ile àgbere. Nwọn jẹ akọ ẹṣin ti a bọ́ rere ti nrin kiri, olukuluku nwọn nyán si aya aladugbo rẹ̀. Emi kì yio ha ṣe ibẹwo nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lara iru orilẹ-ède bi eyi? Ẹ goke lọ si ori odi rẹ̀, ki ẹ si parun; ṣugbọn ẹ máṣe pa a run tan: ẹ wó kùrùkúrù rẹ̀ kuro nitori nwọn kì iṣe ti Oluwa. Nitori ile Israeli ati ile Juda ti huwa arekereke gidigidi si mi, li Oluwa wi. Nwọn sẹ Oluwa, wipe, Kì iṣe on, ibi kò ni wá si ori wa, awa kì yio si ri idà tabi ìyan: Awọn woli yio di ẹfufu, ọ̀rọ kò sì si ninu wọn: bayi li a o ṣe si wọn.

Jer 5:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu, wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀! Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́, tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu. Lóòótọ́ ni wọ́n ń fi orúkọ mi búra pé, “Bí OLUWA tí ń bẹ,” sibẹ èké ni ìbúra wọn. OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́? Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n, o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí. Ojú wọn ti dá, ó le koko, wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada. Nígbà náà ní mo wí lọ́kàn ara mi pé, “Àwọn aláìní nìkan nìwọ̀nyí, wọn kò gbọ́n; nítorí wọn kò mọ ọ̀nà OLUWA, ati òfin Ọlọrun wọn. N óo lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan pataki pataki, n óo sì bá wọn sọ̀rọ̀; nítorí àwọn mọ ọ̀nà OLUWA, ati òfin Ọlọrun wọn.” Ṣugbọn gbogbo wọn náà ni wọ́n ti fa àjàgà wọn dá, tí wọ́n sì ti kọ àṣẹ ati àkóso OLUWA. Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀. Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run. Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn, tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú, yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀, nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun. OLUWA bi Israẹli pé, “Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra. Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán, wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè. Wọ́n dàbí akọ ẹṣin tí a kò tẹ̀ lọ́dàá, tí ó yó, olukuluku wọn ń lé aya aládùúgbò rẹ̀ kiri. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi? Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí? Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run, ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán. Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA. Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA, wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan; ibi kankan kò ní dé bá wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.” Àwọn wolii yóo di àgbá òfo; nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn. Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn.

Jer 5:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu wò yíká, kí o sì mọ̀, kí o sì wá kiri Bí o bá le è rí ẹnìkan, tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo, n ó dáríjì ìlú yìí. Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí OLúWA ti ń bẹ,’ síbẹ̀ wọ́n búra èké.” OLúWA, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́ Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n. Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà. Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí; wọn jẹ́ aṣiwèrè, nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà OLúWA, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́. Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ, n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà OLúWA àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.” Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́, wọ́n sì ti já ìdè. Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n, ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run, ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nítorí àìgbọ́ràn yín pọ, ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀. “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè. Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn. Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni OLúWA wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí? “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti OLúWA. Ilé Israẹli àti ilé Juda ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,” ni OLúWA wí. Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ OLúWA; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn. Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́, ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn. Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”