Jeremiah 20:14-18

Jeremiah 20:14-18 BMYO

Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún. Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé, “A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!” Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí OLúWA gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán. Nítorí kò pa mí nínú, kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi, kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé. Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn, láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀ àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?