Jer 20:14-18

Jer 20:14-18 YBCV

Egbe ni fun ọjọ na ti a bi mi! ọjọ na ti iya mi bi mi, ki o má ri ibukun! Egbe ni fun ọkunrin na ti o mu ihìn tọ̀ baba mi wá, wipe, Ọmọkunrin li a bi fun ọ; o mu u yọ̀. Ki ọkunrin na ki o si dabi ilu wọnni ti Oluwa ti bì ṣubu, li aiyi ọkàn pada, ki o si gbọ́ ẹkun li owurọ, ati ọ̀fọ li ọsangangan. Nitoriti kò pa mi ni inu iya mi, tobẹ̃ ki iya mi di isà mi, ki o loyun mi lailai. Ẽṣe ti emi fi jade kuro ninu iya mi, lati ri irora ati oṣi, ati lati pari ọjọ mi ni itiju?