Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ mí wá wí pé: “Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé:
“Báyìí ni OLúWA wí,
“ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ,
ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ
àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù,
nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
Israẹli jẹ́ mímọ́ sí OLúWA,
àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀,
gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi,
ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ”
bẹ́ẹ̀ ni OLúWA wí.
Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu
àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.
Báyìí ni OLúWA wí:
“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi?
Tí wọ́n fi jìnnà sí mi?
Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,
àwọn fúnrawọn sì di asán.
Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni OLúWA wà,
tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
tí ó mú wa la aginjù já,
tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,
ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,
ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’
Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá
láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,
ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,
‘Níbo ni OLúWA wà?’
Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,
àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.
Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,
wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.
“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”
ni OLúWA wí.
“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ
Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,
ránṣẹ́ lọ sí Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi
kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?
Orílẹ̀-èdè kan ha á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà?
(Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run)
àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀
ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”
ni OLúWA wí.
“Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi
orísun omi ìyè, wọ́n sì ti
ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè
gba omi dúró.
Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀
ẹrú nípa ìbí? Kí ló ha a
dé tí ó fi di ìkógun?
Àwọn kìnnìún ké ramúramù
wọ́n sì ń bú mọ́ wọn
wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò
Ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì
ti di ìkọ̀sílẹ̀.
Bákan náà, àwọn ọkùnrin
Memfisi àti Tafanesi
wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí
ara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀
nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti
láti lọ mu omi ní Ṣihori?
Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria
láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?
Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín
ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí
mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti
ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ
nígbà tí o ti kọ OLúWA Ọlọ́run sílẹ̀,
ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”
ni Olúwa, OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.