Jer 2:1-19
Jer 2:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, Lọ, ki o si ke li eti Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ranti rẹ, iṣeun igbà ọmọde rẹ, ifẹ igbeyawo rẹ, nigbati iwọ tẹle mi ni iju, ni ilẹ ti a kì igbin si. Mimọ́ ni Israeli fun Oluwa, akọso eso oko rẹ̀, ẹnikẹni ti o fi jẹ yio jẹbi; ibi yio si wá si ori wọn, li Oluwa wi. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ara-ile Jakobu, ati gbogbo iran ile Israeli: Bayi li Oluwa wi: Aiṣedede wo li awọn baba nyin ri lọwọ mi ti nwọn lọ jina kuro lọdọ mi, ti nwọn si tẹle asan, ti nwọn si di enia asan? Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si. Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira: Awọn alufa kò wipe, Nibo li Oluwa wà? ati awọn ti o mu ofin lọwọ kò mọ̀ mi: awọn oluṣọ si ṣẹ̀ si mi, ati awọn woli sọ asọtẹlẹ nipa Baali, nwọn si tẹle ohun ti kò lerè. Nitorina, Emi o ba nyin jà, li Oluwa wi, Emi o si ba atọmọde-ọmọ nyin jà. Njẹ, ẹ kọja lọ si erekuṣu awọn ara Kittimu, ki ẹ si wò, si ranṣẹ lọ si Kedari, ki ẹ si ṣe akiyesi gidigidi, ki ẹ wò bi iru nkan yi ba mbẹ nibẹ? Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè. Ki ẹnu ki o ya ọrun nitori eyi, ki o si dãmu, ki o si di gbigbẹ, li Oluwa wi! Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro. Ẹrú ni Israeli iṣe bi? tabi ẹru ibilẹ? ẽṣe ti o fi di ijẹ. Awọn ọmọ kiniun ke ramuramu lori rẹ̀, nwọn si bú, nwọn si sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ilu rẹ̀ li a fi jona li aini olugbe. Awọn ọmọ Nofi ati ti Tafanesi pẹlu ti jẹ agbari rẹ; Fifi Oluwa ọlọrun rẹ silẹ kọ́ ha mu eyi ba ọ, nigbati o tọ́ ọ loju ọ̀na? Njẹ nisisiyi kíni iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Egipti, lati mu omi Sihori? tabi kini iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Assiria lati mu omi odò rẹ̀. Ìwa-buburu rẹ ni yio kọ́ ọ, ipadasẹhin rẹ ni yio si ba ọ wi: mọ̀, ki iwọ si ri i pe, ohun buburu ati kikoro ni, pe, iwọ ti kọ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe ìbẹru mi kò si si niwaju rẹ; li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi.
Jer 2:1-19 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí. Israẹli jẹ́ mímọ́ fún OLUWA Òun ni àkọ́so èso rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ninu àkọ́so èso yìí di ẹlẹ́bi; ibi sì dé bá wọn. Èmi OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ilé Jakọbu, ati gbogbo ìdílé Israẹli. OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán? Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà, ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já, ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun, ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kì í gbé? Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá, pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀, ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́, ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra. Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’ Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí, àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi, àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn. “Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́, n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká, tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní, bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí. Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́? Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn, wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀. Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run, kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.” OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji: wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀, wọ́n ṣe kànga fún ara wọn; kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró. “Ṣé ẹrú ni Israẹli ni, àbí ọmọ ẹrú tí ẹrú bí sinu ilé? Báwo ló ṣe wá di ìjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. Àwọn kinniun ti bú mọ́ ọn, wọ́n bú ramúramù. Wọ́n sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro. Àwọn ìlú rẹ̀ sì ti tú, wọ́n ti wó palẹ̀, láìsí eniyan tí ń gbé inú wọn. Bákan náà, àwọn ará Memfisi ati Tapanhesi ti fọ́ adé orí rẹ̀. Ṣebí ọwọ́ ara yín ni ẹ fi fà á sí orí ara yín, nígbà tí ẹ̀yin kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, nígbà tí ó ń tọ yín sọ́nà? Kí ni èrè tí ẹ rí nígbà tí ẹ lọ sí Ijipti, tí ẹ lọ mu omi odò Naili, àbí kí ni èrè tí ẹ gbà bọ̀ nígbà tí ẹ lọ sí Asiria, tí ẹ lọ mu omi odò Yufurate. Ìwà burúkú yín yóo fìyà jẹ yín, ìpadà sẹ́yìn yín yóo sì kọ yín lọ́gbọ́n. Kí ó da yín lójú pé, nǹkan burúkú ni, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kò sì ní dùn, pé ẹ fi èmi OLUWA Ọlọrun yín sílẹ̀; ìbẹ̀rù mi kò sí ninu yín. Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Jer 2:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ mí wá wí pé: “Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé: “Báyìí ni OLúWA wí, “ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ, ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù, nínú ìyàngbẹ ilẹ̀. Israẹli jẹ́ mímọ́ sí OLúWA, àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ” bẹ́ẹ̀ ni OLúWA wí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli. Báyìí ni OLúWA wí: “Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi? Tí wọ́n fi jìnnà sí mi? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán, àwọn fúnrawọn sì di asán. Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni OLúWA wà, tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, tí ó mú wa la aginjù já, tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò, ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’ Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́, ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra. Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé, ‘Níbo ni OLúWA wà?’ Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi. Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán. “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,” ni OLúWA wí. “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó, ránṣẹ́ lọ sí Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀? Orílẹ̀-èdè kan ha á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà? (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run) àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì. Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni OLúWA wí. “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró. Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí? Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun? Àwọn kìnnìún ké ramúramù wọ́n sì ń bú mọ́ wọn wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò Ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀. Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ. Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà? Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti láti lọ mu omi ní Ṣihori? Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà? Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ nígbà tí o ti kọ OLúWA Ọlọ́run sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,” ni Olúwa, OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.