Jakọbu 1:5-11

Jakọbu 1:5-11 YCB

Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè. Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa; Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìlèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga. Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ. Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.