JAKỌBU 1:5-11

JAKỌBU 1:5-11 YCE

Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún. Ṣugbọn olúwarẹ̀ níláti bèèrè pẹlu igbagbọ, láì ṣiyèméjì. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì omi òkun, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri tí ó sì ń rú sókè. Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé òun óo rí nǹkankan gbà lọ́dọ̀ Oluwa: ọkàn rẹ̀ kò papọ̀ sí ọ̀nà kan, ó ń ṣe ségesège, ó ń ṣe iyè meji. Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga. Bẹ́ẹ̀ ni kí ọlọ́rọ̀ kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, nítorí bí òdòdó koríko ìgbẹ́ ni ọlọ́rọ̀ kò ní sí mọ́. Nítorí nígbà tí oòrùn bá yọ, tí ó mú, koríko á rọ, òdòdó rẹ̀ á sì rẹ̀, òdòdó tí ó lẹ́wà tẹ́lẹ̀ á wá ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọlọ́rọ̀ yóo parẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.