Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.
Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.
Lẹ́yìn èyí, OLúWA sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀. Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Resini àti Aramu àti ti ọmọ Remaliah. Aramu, Efraimu àti Remaliah ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé, “Jẹ́ kí a kọlu Juda; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrín ara wa, kí a sì fi ọmọ Tabeli jẹ ọba lórí i rẹ̀.” Síbẹ̀ èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí:
“ ‘Èyí kò ní wáyé
èyí kò le ṣẹlẹ̀,
nítorí Damasku ni orí Aramu,
orí Damasku sì ni Resini.
Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́ta
Efraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
Orí Efraimu sì ni Samaria,
orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah.
Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́,
lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’ ”
Bákan náà OLúWA tún bá Ahasi sọ̀rọ̀, “Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ OLúWA Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.”
Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán OLúWA wò.”