Isa 7:1-12
Isa 7:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe li ọjọ Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah, ọba Juda, ti Resini, ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah, ọba Israeli, gokè lọ si Jerusalemu lati jà a li ogun, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀. A si sọ fun ile Dafidi pe, Siria ba Efraimu dìmọlú. Ọkàn rẹ̀ si mì, ati ọkàn awọn enia rẹ̀ bi igi igbo ti imì nipa ẹfũfu. Oluwa si sọ fun Isaiah pe, Jade nisisiyi, lọ ipade Ahasi, iwọ, ati Ṣeaja-ṣubu ọmọ rẹ, ni ipẹkun oju iṣàn ikũdu ti apa oke, li opopo pápa afọṣọ; Si sọ fun u pe, Kiyesara, ki o si gbe jẹ, má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe jaiya nitori ìru meji igi iná ti nrú ẹ̃fin wọnyi nitori ibinu mimuna Resini pẹlu Siria, ati ti ọmọ Remaliah. Nitori Siria, Efraimu, ati ọmọ Remaliah ti gbìmọ ibi si ọ wipe. Ẹ jẹ ki a gòke lọ si Juda, ki a si bà a ninu jẹ, ẹ si jẹ ki a ṣe ihò ninu rẹ̀ fun ara wa, ki a si gbe ọba kan kalẹ lãrin rẹ̀, ani ọmọ Tabeali: Bayi ni Oluwa Jehofah wi, Ìmọ na kì yio duro, bẹ̃ni ki yio ṣẹ. Nitori ori Siria ni Damasku, ori Damasku si ni Resini; ninu ọdun marunlelọgọta li a o fọ Efraimu ti ki yio si jẹ́ enia mọ. Ori Efraimu si ni Samaria, ori Samaria si ni ọmọ Remaliah. Bi ẹnyin ki yio ba gbagbọ́, lotitọ, a ki yio fi idi nyin mulẹ. Oluwa si tun sọ fun Ahasi pe, Bere àmi kan lọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ; bere rẹ̀, ibã jẹ ni ọgbun tabi li okè. Ṣugbọn Ahasi wipe, Emi ki yio bere, bẹ̃ni emi ki yio dán Oluwa wò.
Isa 7:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀. Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó. OLUWA sọ fún Aisaya pé, “Lọ bá Ahasi, ìwọ ati Ṣeari Jaṣubu, ọmọ rẹ, ní òpin ibi tí wọ́n fa omi dé ní ọ̀nà àwọn alágbàfọ̀. Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín. Nítorí pé Siria, pẹlu Efuraimu ati ọmọ Remalaya ti pète ati ṣe ọ́ ní ibi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun ti Juda, kí á dẹ́rùbà á, ẹ jẹ́ kí á ṣẹgun rẹ̀ kí á sì gbà á, kí á fi ọmọ Tabeeli jọba lórí rẹ̀!’ “Àbá tí wọn ń dá kò ní ṣẹ, ète tí wọn ń pa kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́. Ṣebí Samaria ni olú-ìlú Efuraimu, Ọmọ Remalaya sì ni olórí Samaria. Bí ẹ kò bá gbàgbọ́ ẹ kò ní fẹsẹ̀ múlẹ̀.” OLUWA tún sọ fún Ahasi pé: “Bèèrè àmì tí ó bá wù ọ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ–ìbáà jìn bí isà òkú, tabi kí ó ga bí ojú ọ̀run.” Ṣugbọn Ahasi dáhùn, ó ní: “Èmi kò ní bèèrè nǹkankan, n kò ní dán OLUWA wò.”
Isa 7:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀. Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́. Lẹ́yìn èyí, OLúWA sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀. Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Resini àti Aramu àti ti ọmọ Remaliah. Aramu, Efraimu àti Remaliah ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé, “Jẹ́ kí a kọlu Juda; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrín ara wa, kí a sì fi ọmọ Tabeli jẹ ọba lórí i rẹ̀.” Síbẹ̀ èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: “ ‘Èyí kò ní wáyé èyí kò le ṣẹlẹ̀, nítorí Damasku ni orí Aramu, orí Damasku sì ni Resini. Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́ta Efraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́. Orí Efraimu sì ni Samaria, orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah. Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́, lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’ ” Bákan náà OLúWA tún bá Ahasi sọ̀rọ̀, “Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ OLúWA Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.” Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán OLúWA wò.”