Esra 9:1-5

Esra 9:1-5 YCB

Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori. Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.” Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo tu irun orí àti irùngbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìjayà. Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó wárìrì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Israẹli kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìjayà títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́. Ní ìgbà tí ó di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí OLúWA Ọlọ́run mi.