Esr 9:1-5
Esr 9:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI a si ti ṣe nkan wọnyi tan, awọn ijoye wá si ọdọ mi, wipe, Awọn enia Israeli, ati awọn alufa, pẹlu awọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn si ọ̀tọ kuro ninu awọn enia ilẹ wọnni, gẹgẹ bi irira wọn, ti awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Perisi, awọn ara Jebusi, awọn ara Ammoni, awọn ara Moabu, awọn ara Egipti, ati ti awọn ara Amori. Nitoripe nwọn mu awọn ọmọ wọn obinrin fun aya wọn, ati fun awọn ọmọ wọn ọkunrin: tobẹ̃ ti a da iru-ọmọ mimọ́ pọ̀ mọ awọn enia ilẹ wọnni: ọwọ awọn ijoye, ati awọn olori si ni pataki ninu irekọja yi. Nigbati mo si gbọ́ nkan wọnyi, mo fa aṣọ mi ati agbáda mi ya, mo si fà irun ori mi ati ti àgbọn mi tu kuro, mo si joko ni ijaya. Nigbana ni olukuluku awọn ti o warìri si ọ̀rọ Ọlọrun Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ mi, nitori irekọja awọn wọnni ti a ti ko lọ; mo si joko ni ijaya titi di igba ẹbọ aṣalẹ. Ni igba ẹbọ aṣalẹ ni mo si dide kuro ninu ikãnu mi; pẹlu aṣọ ati agbáda mi yiya, mo si wolẹ lori ẽkun mi, mo si nà ọwọ mi si Oluwa Ọlọrun mi.
Esr 9:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n ní: “Àwọn ọmọ Israẹli pẹlu àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò ninu ìwà ìríra àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi ati àwọn ará Jebusi, ti àwọn ará Amoni ati àwọn ará Moabu, àwọn ará Ijipti, ati àwọn ará Amori. Wọ́n ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn fún ara wọn ati fún àwọn ọmọ wọn; àwọn ẹ̀yà mímọ́ sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà jù ni àwọn olórí ati àwọn eniyan pataki ní Israẹli.” Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fa aṣọ ati agbádá mi ya, láti fi ìbànújẹ́ mi hàn, mo sì fa irun orí ati irùngbọ̀n mi tu; mo sì jókòó pẹlu ìbànújẹ́. Mo jókòó bẹ́ẹ̀ títí di àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ̀gbà yí mi ká nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé. Ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́, mo dìde kúrò níbi tí mo ti ń gbààwẹ̀ pẹlu aṣọ ati agbádá mi tí ó ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ sí OLUWA Ọlọrun mi, mo gbadura pé
Esr 9:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori. Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.” Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo tu irun orí àti irùngbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìjayà. Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó wárìrì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Israẹli kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìjayà títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́. Ní ìgbà tí ó di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí OLúWA Ọlọ́run mi.