Eksodu 18:1-12

Eksodu 18:1-12 YCB

Jetro, àlùfáà Midiani, àna Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mose àti fún Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí OLúWA ti mú àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Ejibiti wá. Nígbà náà ni Jetro mu aya Mose tí í ṣe Sippora padà lọ sọ́dọ̀ rẹ (Nítorí ó ti dá a padà sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀). Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ Àkọ́bí ń jẹ́ Gerṣomu (àjèjì); nítorí Mose wí pé, “Èmi ń ṣe àlejò ni ilẹ̀ àjèjì.” Èkejì ń jẹ́ Elieseri (alátìlẹ́yìn); ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Farao.” Jetro, àna Mose, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mose tọ̀ ọ́ wá nínú aginjù tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run. Jetro sì ti ránṣẹ́ sí Mose pé, “Èmi Jetro, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.” Mose sì jáde lọ pàdé àna rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n sì béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. Mose sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti OLúWA tí ṣe sí Farao àti àwọn ará Ejibiti nítorí Israẹli. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí OLúWA ti gbà wọ́n là. Inú Jetro dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti OLúWA ṣe fún Israẹli, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Jetro sì wí pé, “Ìyìn ni fún OLúWA, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti àti lọ́wọ́ Farao, ẹni tí ó sì gba àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti. Mo mọ nísinsin yìí pé OLúWA tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Ejibiti.” Jetro, àna Mose, mú ẹbọ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Aaroni àti gbogbo àgbàgbà Israẹli sì wá láti bá àna Mose jẹun ní iwájú Ọlọ́run.