Eks 18:1-12
Eks 18:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Jetro, alufa Midiani, ana Mose, gbọ́ ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun Mose, ati fun Israeli awọn enia rẹ̀, ati pe, OLUWA mú Israeli lati Egipti jade wá; Nigbana ni Jetro, ana Mose, mú Sippora aya Mose wá, lẹhin ti o ti rán a pada. Ati awọn ọmọ rẹ̀ mejeji: ti orukọ ọkan njẹ Gerṣomu; nitoriti o wipe, Emi ṣe alejò ni ilẹ ajeji. Ati orukọ ekeji ni Elieseri; nitoriti o wipe, Ọlọrun baba mi li alatilẹhin mi, o si gbà mi lọwọ idà Farao: Ati Jetro, ana Mose, o tọ̀ Mose wá ti on ti awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀ si ijù, nibiti o gbé dó si lẹba oke Ọlọrun. O si wi fun Mose pe, Emi Jetro ana rẹ li o tọ̀ ọ wá, pẹlu aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ̀. Mose si jade lọ ipade ana rẹ̀, o si tẹriba, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, nwọn si bére alafia ara wọn; nwọn si wọ̀ inu agọ́. Mose si sọ ohun gbogbo ti OLUWA ti ṣe si Farao, ati si awọn ara Egipti nitori Israeli fun ana rẹ̀, ati gbogbo ipọnju ti o bá wọn li ọ̀na, ati bi OLUWA ti gbà wọn. Jetro si yọ̀ nitori gbogbo ore ti OLUWA ti ṣe fun Israeli, ẹniti o ti gbàla lọwọ awọn ara Egipti. Jetro si wipe, Olubukún li OLUWA, ẹniti o gbà nyin là lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ Farao, ẹniti o gbà awọn enia là lọwọ awọn ara Egipti. Mo mọ̀ nisisiyi pe OLUWA tobi jù gbogbo oriṣa lọ: nitõtọ, ninu ọ̀ran ti nwọn ti ṣeféfe si wọn. Jetro, ana Mose, si mù ẹbọ sisun, ati ẹbọ wá fun Ọlọrun: Aaroni si wá, ati gbogbo awọn àgba Israeli, lati bá ana Mose jẹun niwaju Ọlọrun.
Eks 18:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Jẹtiro, alufaa àwọn ará Midiani, baba iyawo Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọrun ti ṣe fún Mose ati fún Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀, ati bí ó ti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Jẹtiro, baba iyawo Mose mú Sipora aya Mose, lẹ́yìn tí Mose ti dá a pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji. Orúkọ ọmọ rẹ̀ kinni ni Geriṣomu, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Mo ti jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”) Orúkọ ọmọ keji ni Elieseri, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ọlọrun baba mi ni olùrànlọ́wọ́ mi, òun ni ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ idà Farao.”) Jẹtiro, baba iyawo Mose, mú iyawo Mose, ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tọ̀ ọ́ wá ní aṣálẹ̀, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí níbi òkè Ọlọrun. Nígbà tí wọ́n sọ fún Mose pé Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Mose lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀ níwájú Jẹtiro, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n bèèrè alaafia ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. Gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe sí Farao ati sí àwọn ará Ijipti nítorí àwọn ọmọ Israẹli ni Mose ròyìn fún baba iyawo rẹ̀. Ó sọ gbogbo ìṣòro tí wọ́n rí lójú ọ̀nà, ati bí OLUWA ti kó wọn yọ. Jẹtiro sì bá wọn yọ̀ nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí gbígbà tí ó gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti. Jẹtiro dáhùn, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA, tí ó gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati lọ́wọ́ Farao. Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.” Jẹtiro bá rú ẹbọ sísun sí Ọlọrun. Aaroni ati àwọn àgbààgbà Israẹli sì wá sọ́dọ̀ Jẹtiro, láti bá a jẹun níwájú Ọlọrun.
Eks 18:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jetro, àlùfáà Midiani, àna Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mose àti fún Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí OLúWA ti mú àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Ejibiti wá. Nígbà náà ni Jetro mu aya Mose tí í ṣe Sippora padà lọ sọ́dọ̀ rẹ (Nítorí ó ti dá a padà sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀). Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ Àkọ́bí ń jẹ́ Gerṣomu (àjèjì); nítorí Mose wí pé, “Èmi ń ṣe àlejò ni ilẹ̀ àjèjì.” Èkejì ń jẹ́ Elieseri (alátìlẹ́yìn); ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Farao.” Jetro, àna Mose, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mose tọ̀ ọ́ wá nínú aginjù tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run. Jetro sì ti ránṣẹ́ sí Mose pé, “Èmi Jetro, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.” Mose sì jáde lọ pàdé àna rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n sì béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. Mose sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti OLúWA tí ṣe sí Farao àti àwọn ará Ejibiti nítorí Israẹli. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí OLúWA ti gbà wọ́n là. Inú Jetro dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti OLúWA ṣe fún Israẹli, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Jetro sì wí pé, “Ìyìn ni fún OLúWA, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti àti lọ́wọ́ Farao, ẹni tí ó sì gba àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti. Mo mọ nísinsin yìí pé OLúWA tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Ejibiti.” Jetro, àna Mose, mú ẹbọ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Aaroni àti gbogbo àgbàgbà Israẹli sì wá láti bá àna Mose jẹun ní iwájú Ọlọ́run.