Eksodu 15:1-12

Eksodu 15:1-12 BMYO

Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLúWA, Èmi yóò kọrin sí OLúWA, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun. OLúWA ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. Ológun ni OLúWA, OLúWA ni orúkọ rẹ, kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun Pupa. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLúWA, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLúWA, fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko. Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun. Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé, ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. èmi ó pín ìkógun; èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’ Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá. Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, OLúWA? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn, tí ń ṣe ohun ìyanu? “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ si gbé wọn mì.