Eks 15:1-12

Eks 15:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní: “N óo kọrin sí OLUWA, nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo. Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa. OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi, n óo máa yìn ín. Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi; n óo máa gbé e ga. Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀. Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun, ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa. Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta. Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA; OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. Ninu títóbi ọláńlá rẹ, o dojú àwọn ọ̀tá rẹ bolẹ̀, o fa ibinu yọ, ó sì jó wọn bí àgékù koríko. Èémí ihò imú rẹ mú kí omi gbájọ, ìkún omi dúró lóòró bí òkítì, ibú omi sì dì ní ìsàlẹ̀ òkun. Ọ̀tá wí pé, ‘N óo lé wọn, ọwọ́ mi yóo sì tẹ̀ wọ́n; n óo pín ìkógun, n óo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn lára wọn. N óo fa idà mi yọ, ọwọ́ mi ni n óo sì fi pa wọ́n run.’ Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n, òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá. “Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa? Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ? Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu. O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì.

Eks 15:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLúWA, Èmi yóò kọrin sí OLúWA, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun. OLúWA ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. Ológun ni OLúWA, OLúWA ni orúkọ rẹ, kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun Pupa. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLúWA, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLúWA, fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko. Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun. Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé, ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. èmi ó pín ìkógun; èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’ Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá. Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, OLúWA? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn, tí ń ṣe ohun ìyanu? “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ si gbé wọn mì.