Oniwaasu 10:1-9

Oniwaasu 10:1-9 YCB

Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú, bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀. Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára. Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà, òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó. Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ, ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀; ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá. Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso. A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ, nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ. Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin, nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn; ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.