ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 10:1-9

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 10:1-9 YCE

Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́; bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́. Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere, ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí. Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n, a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó. Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ, má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ, ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini. Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe: Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀. Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú. Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀, ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ. Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára; ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba.