Oni 10:1-9
Oni 10:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OKÚ eṣinṣin o mu ororo-ikunra alapolu bajẹ ki o ma run õrùn buburu: bẹ̃ni wère diẹ wuwo jù ọgbọ́n ati ọlá lọ. Aiya ọlọgbọ́n mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ṣugbọn aiya aṣiwère li ọwọ òsi rẹ̀. Ati pẹlu nigbati ẹniti o ṣiwère ba nrìn li ọ̀na, ọgbọ́n rẹ̀ a fò lọ, on a si wi fun olukuluku enia pe aṣiwère li on. Bi ọkàn ijoye ba ru si ọ, máṣe fi ipò rẹ silẹ; nitoripe itũbá ama tù ẹ̀ṣẹ nla. Buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, bi ìṣina ti o ti ọdọ awọn ijoye wá. A gbe aṣiwère sipò ọlá, awọn ọlọrọ̀ si joko nipò ẹhin. Mo ri awọn ọmọ-ọdọ lori ẹṣin, ati awọn ọmọ-alade nrìn bi ọmọ-ọdọ ni ilẹ. Ẹniti o wà iho ni yio bọ́ sinu rẹ̀; ati ẹniti o si njá ọgbà tútù, ejo yio si bù u ṣán. Ẹnikan ti o nyi okuta ni yio si ti ipa rẹ̀ ni ipalara; ati ẹniti o si nla igi ni yio si wu li ewu.
Oni 10:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́; bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́. Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere, ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí. Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n, a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó. Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ, má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ, ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini. Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe: Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀. Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú. Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀, ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ. Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára; ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba.
Oni 10:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú, bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀. Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára. Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà, òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó. Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ, ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀; ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá. Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso. A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ, nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ. Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin, nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn; ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.