Ìṣe àwọn Aposteli 25:6-7

Ìṣe àwọn Aposteli 25:6-7 BMYO

Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesarea, ni ọjọ́ kejì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Paulu wá síwájú òun. Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.