Iṣe Apo 25:6-7
Iṣe Apo 25:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kò si gbe ãrin wọn ju ijọ mẹjọ tabi mẹwa lọ, o sọkalẹ lọ si Kesarea; ni ijọ keji o joko lori itẹ́ idajọ, o si paṣẹ pè ki a mu Paulu wá. Nigbati o si de, awọn Ju ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá duro yi i ká, nwọn nkà ọ̀ran pipọ ti o si buru si Paulu lọrùn, ti nwọn kò le ladi.
Iṣe Apo 25:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Kò lò ju bí ọjọ́ mẹjọ tabi mẹ́wàá lọ pẹlu wọn, ni ó bá pada lọ sí Kesaria. Ní ọjọ́ keji ó jókòó ninu kóòtù, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wá. Nígbà tí Paulu dé, àwọn Juu tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu tò yí i ká, wọ́n ń ro ẹjọ́ ńláńlá mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ninu gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò.
Iṣe Apo 25:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesarea, ni ọjọ́ kejì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Paulu wá síwájú òun. Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.