Ìṣe àwọn Aposteli 2:24-28

Ìṣe àwọn Aposteli 2:24-28 BMYO

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú, nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú. Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, a kì ó ṣí mi ní ipò. Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí. Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́. Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè, ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’