Iṣe Apo 2:24-28

Iṣe Apo 2:24-28 YBCV

Ẹniti Ọlọrun gbé dide, nigbati o ti tú irora ikú: nitoriti kò ṣe iṣe fun u lati dì i mu. Nitori Dafidi ti wi nipa tirẹ̀ pe, Mo ri Oluwa nigba-gbogbo niwaju mi, nitoriti o mbẹ li ọwọ́ ọtún mi, ki a mà bà ṣí mi ni ipò: Nitorina inu mi dùn, ahọn mi si yọ̀; pẹlupẹlu ara mi yio si simi ni ireti: Nitoriti iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú, bẹ̃ni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni-Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ. Iwọ mu mi mọ̀ ọ̀na iye; iwọ ó mu mi kún fun ayọ̀ ni iwaju rẹ.