Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀. Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi nítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú. Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí, sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí; nítorí o kò ní fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú; bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí, O óo sì fi ayọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’
Kà ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:24-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò