1 Kronika 1:7-12

1 Kronika 1:7-12 YCB

Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Misraimu, Puti, àti Kenaani. Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Ṣabteka. Àwọn ọmọ Raama: Ṣeba àti Dedani. Kuṣi sì bí Nimrodu: Ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé. Misraimu sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu, Patrusimu, Kasluhimu, (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.