I. Kro 1:7-12
I. Kro 1:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu. Awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, Puti, ati Kenaani. Ati awọn ọmọ Kuṣi; Ṣeba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka. Ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba ati Dedani. Kuṣi si bi Nimrodu: on bẹ̀rẹ si di alagbara li aiye. Misraimu si bi Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu, Ati Patrusimu, ati Kasluhimu, (lọdọ ẹniti awọn ara Filistia ti wá,) ati Kaftorimu.
I. Kro 1:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Jafani ni baba ńlá àwọn ọmọ Eliṣa, Taṣiṣi, ati àwọn ará Kitimu, ati Rodọni. Hamu ni baba Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani, Kuṣi bí Ṣeba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka; Raama ni baba Ṣeba ati Dedani, Kuṣi bí Nimrodu. Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí ó di akikanju ati alágbára lórí ilẹ̀ ayé. Ijipti ni baba àwọn ará Lidia ati ti Anamu, ti Lehabu, ati ti Nafitu; àwọn ará Patirusimu ati ti Kasilu tíí ṣe baba ńlá àwọn ará Filistia ati àwọn ará Kafito.
I. Kro 1:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Misraimu, Puti, àti Kenaani. Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Ṣabteka. Àwọn ọmọ Raama: Ṣeba àti Dedani. Kuṣi sì bí Nimrodu: Ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé. Misraimu sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu, Patrusimu, Kasluhimu, (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.