Sek 7:7-11

Sek 7:7-11 YBCV

Wọnyi kì ọ̀rọ ti Oluwa ti kigbe lati ọdọ awọn woli iṣãju wá, nigbati a ngbe Jerusalemu, ti o si wà li alafia, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ti o yi i ka kiri, nigbati a ngbe gusù ati pẹtẹlẹ? Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Sekariah wá, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀. Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀. Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́.