Sek 7:7-11
Sek 7:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wọnyi kì ọ̀rọ ti Oluwa ti kigbe lati ọdọ awọn woli iṣãju wá, nigbati a ngbe Jerusalemu, ti o si wà li alafia, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ti o yi i ka kiri, nigbati a ngbe gusù ati pẹtẹlẹ? Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Sekariah wá, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀. Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀. Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́.
Sek 7:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀? OLUWA tún rán Sakaraya kí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì fi àánú ati ìyọ́nú hàn sí ara yín. Ẹ má máa fi ìyà jẹ àwọn opó, tabi àwọn aláìníbaba, tabi àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tabi àwọn aláìní. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ẹnikẹ́ni.” Ṣugbọn àwọn eniyan kò gbọ́, wọ́n ṣe oríkunkun, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ tèmi.
Sek 7:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti OLúWA ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ” Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Sekariah wá, wí pé: “Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀. Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’ “Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́.