Rom 9:6-18

Rom 9:6-18 YBCV

Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli: Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ. Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ. Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin. Kì si iṣe kìki eyi; ṣugbọn nigbati Rebekka pẹlu lóyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa; Nitori nigbati a kò ti ibí awọn ọmọ na, bẹ̃ni nwọn kò ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti iyanfẹ ki o le duro, kì iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npè ni;) A ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio ma sìn aburo, Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakọbu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira. Njẹ awa o ha ti wi? Aiṣododo ha wà lọdọ Ọlọrun bi? Ki a má ri. Nitori o wi fun Mose pe, Emi ó ṣãnu fun ẹniti emi ó ṣãnu fun, emi o si ṣe iyọ́nu fun ẹniti emi o ṣe iyọ́nu fun. Njẹ bẹ̃ni kì iṣe ti ẹniti o fẹ, kì si iṣe ti ẹniti nsáre, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣãnu. Nitori iwe-mimọ́ wi fun Farao pe, Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mã ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. Nitorina li o ṣe nṣãnu fun ẹniti o wù u, ẹniti o wù u a si mu u li ọkàn le.