Rom 9:6-18
Rom 9:6-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli: Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ. Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ. Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin. Kì si iṣe kìki eyi; ṣugbọn nigbati Rebekka pẹlu lóyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa; Nitori nigbati a kò ti ibí awọn ọmọ na, bẹ̃ni nwọn kò ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti iyanfẹ ki o le duro, kì iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npè ni;) A ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio ma sìn aburo, Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakọbu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira. Njẹ awa o ha ti wi? Aiṣododo ha wà lọdọ Ọlọrun bi? Ki a má ri. Nitori o wi fun Mose pe, Emi ó ṣãnu fun ẹniti emi ó ṣãnu fun, emi o si ṣe iyọ́nu fun ẹniti emi o ṣe iyọ́nu fun. Njẹ bẹ̃ni kì iṣe ti ẹniti o fẹ, kì si iṣe ti ẹniti nsáre, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣãnu. Nitori iwe-mimọ́ wi fun Farao pe, Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mã ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. Nitorina li o ṣe nṣãnu fun ẹniti o wù u, ẹniti o wù u a si mu u li ọkàn le.
Rom 9:6-18 Yoruba Bible (YCE)
Sibẹ, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kùnà patapata. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bí sinu ìdílé Israẹli ni ọmọ Israẹli tòótọ́. Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ìran Abrahamu ni ọmọ rẹ̀ tòótọ́, nítorí bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Àwọn ọmọ Isaaki nìkan ni a óo kà sí ìran fún ọ.” Èyí ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ tí a bí nípa ti ara lásán ni ọmọ Ọlọrun. Àwọn ọmọ tí a bí nípa ìlérí Ọlọrun ni a kà sí ìran Abrahamu. Nítorí báyìí ni ọ̀rọ̀ ìlérí náà: “Nígbà tí mo bá pada wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóo ti bí ọmọkunrin kan.” Èyí nìkan kọ́. Rebeka bímọ meji fún ẹnìkan ṣoṣo, òun náà ni baba wa Isaaki. Ṣugbọn kí á tó bí àwọn ọmọ náà, àní sẹ́, kí wọ́n tó dá ohunkohun ṣe, yálà rere ni tabi burúkú, ni Ọlọrun ti sọ fún Rebeka pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo máa ṣe iranṣẹ àbúrò rẹ̀.” Báyìí ni Ọlọrun ti ń ṣe ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé, nígbà tí ó bá yan àwọn kan. Ó wá hàn kedere pé Ọlọrun kì í wo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan kí ó tó yàn wọ́n; àwọn tí ó bá pinnu tẹ́lẹ̀ láti yàn ní í pè. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Jakọbu ni mo yàn, Esau ni mo kọ̀.” Kí ni kí á wá wí sí èyí? Kí á wí pé Ọlọrun ń ṣe àìdára ni bí? Rárá o! Nítorí ó sọ fún Mose pé, “Ẹni tí mo bá fẹ́ ṣàánú ni n óo ṣàánú; ẹni tí mo bá sì fẹ́ yọ́nú sí ni n óo yọ́nú sí.” Nítorí náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí eniyan ti fẹ́ tabi bí ó ti gbìyànjú tó ni Ọlọrun fi ń yàn án, bí ó bá ti wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ ni. Nítorí Ọlọrun sọ ninu Ìwé Mímọ́ nípa Farao pé, “Ìdí tí mo fi fi ọ́ jọba ni pé, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe àpẹẹrẹ bí agbára mi ti tó, ati pé kì ìròyìn orúkọ mi lè tàn ká gbogbo ayé.” Nítorí náà, ẹni tí ó bá wu Ọlọrun láti ṣàánú, a ṣàánú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì wù ú láti dí lọ́kàn, a dí i lọ́kàn.
Rom 9:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli: Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ: Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.” Kì í sì í ṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa. Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.” Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! Nítorí ó wí fún Mose pé, “Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.” Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.