Rom 3:27-31

Rom 3:27-31 YBCV

Ọna iṣogo da? A ti mu u kuro. Nipa ofin wo? ti iṣẹ? Bẹ́kọ: ṣugbọn nipa ofin igbagbọ́. Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin. Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu: Bi o ti jẹ pe Ọlọrun kan ni, ti yio da awọn akọla lare nipa igbagbọ́, ati awọn alaikọla nitori igbagbọ́ wọn. Awa ha nsọ ofin dasan nipa igbagbọ́ bi? Ki a má ri: ṣugbọn a nfi ofin mulẹ.